Search

Wednesday 6 January 2016

Baba, a tun pade l'oko Jesu


Baba, a tun pade l'oko Jesu

Verse 1
Baba, a tun pade l'oko Jesu
A si wa teriba lab'ese Re
A tun fe gb'ohun wa soke si O
Lati wa anu, lati korin 'yin

Verse 2
A yin O fun itoju 'gbagbogbo
Ojojumo l'ao ma rohin 'se re
Wiwa laye wa, anu Re ha ko?
Apa Re ki o fi ngba ni mora?

Verse 3
O se! A ko ye ife nla Re
A sako kuro lodo Re poju
Sugbon kikankikan ni O si npe
Nje a de, a pada wa 'le, Baba

Verse 4
Nipa oko t'o bor'ohun gbogbo
Nipa ife t'o ta 'fe gbogbo yo
Nipa eje ti a ta fun ese
Silekun anu si gbani si 'le
AMIN

English Translation: Father, again in Jesus' name we meet

Lekan si bi orun ti nran

Lekan si bi orun ti nran

Jesu, Orun Ododo

Jesu Orun Ododo

Krisi, Ologo, Olola



Krisit, Ologo, Olola

Tuesday 13 October 2015

Ogo ni f'Oluwa t'o se ohun nla

Verse 1
Ogo ni f'Oluwa t'o se ohun nla
Ife lo mu k'O fun wa ni omo Re
Eni t'O f'emi Re lele f'ese wa
T'o si silekun iye sile fun wa

Chorus
Yin  Oluwa, Yin Oluwa
F'iyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa
Eyo niwaju Re
K'a to Baba wa lo l'Oruko Jesu
Jek'a joo f'ogo fun, Onise 'yanu

Verse 2
Irapada kikun ti eje Re ra
F'eneikeni t'o gba ileri Re gbo
Enit' o buruju b'o ba le gbagbo
Lojukannna yo ri idariji gba

Chorus
Yin  Oluwa, Yin Oluwa
F'iyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa
Eyo niwaju Re
K'a to Baba wa lo l'Oruko Jesu
Jek'a joo f'ogo fun, Onise 'yanu

Verse 3
O s'ohun nla fun wa, o da wa l'ola
Ayo wa di kikun ninu Omo Re
Ogo ati ewa irapada yi
Y'oya wa lenu 'gbata ba ri Jesu

English-To God be the glory

Eje k’a f’inu didun

Verse 1
Eje k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 2
On nipa agbara Re
F’imole s’aye titun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 3
O mbo gbogb’eda ‘laye
O npese fun aini won
Anu re, O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 4
O npese f’ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu re O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 5
E je k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju.

English-Let us with a gladsome mind