Search

Showing posts with label GBOGBO aye gbe Jesu. Show all posts
Showing posts with label GBOGBO aye gbe Jesu. Show all posts

Tuesday, 13 October 2015

GBOGBO aye, gbe Jesu ga

Verse 1
GBOGBO aye, gbe Jesu ga,
Angel, e wole fun;
E mu ade Oba Re wa,
Se l'Oba awon Oba.


Verse 2
E se l'Oba, eyin Martyr,
Ti n pe ni pepe Re;
Gbe gbongbon-igi Jesse ga,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 3
Eyin iru-omo Israel,
Ti a ti rapada;
E ki eni t'o gba yin la,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 4
Gbogbo eniyan elese,
Ranti 'banuje yin;
E te 'kogun yin s'ese Re,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 5
Ki gbogbo orile-ede,
Ni gbogbo agbaye;
Ki won ki, “Kabiyesile”,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 6
A bale pel'awon t'orun,
Lati ma juba Re;
K'a ba le jo jumo korin,
Se l'Oba awon Oba.


English-All hail the power of Jesus' name