Search

Showing posts with label OLORI Ijo t'orun. Show all posts
Showing posts with label OLORI Ijo t'orun. Show all posts

Tuesday, 13 October 2015

OLORI Ijo t'orun

Verse 1
OLORI Ijo t'orun,
L'ayo l'a wole fun o,
K'O to de, Ijo t'aye,
A gbe okan wa s'oke,
Ni 'reti t'o ni 'bukun;
Awa kigbe, awa f'iyin,
F'olorun igbala wa.

Verse 2
'Gba t'a wa ninu iponju,
T'a n koja ninu ina,
Orin ife l'awa o ko,
Ti o n mu wa sunmo o,
Awa sope, a si yo,
Ninu ojurere Re;
Ife t'o so wa di Tire;
Y'o se wa ni Tire lai.

Verse 3
Iwo mu awon eniyan Re,
Koja isan idanwo;
A ki o beru wahala,
'Tori O wa nitosi;
Aye, ese, at'esu,
Koju 'ja si wa lasan,
L'agbara Re, a o segun,
A o si ko orin Mose.

Verse 4
Awa f'igbagbo r'ogo,
T'O tun n fe fi wa si:
A kegan aye 'tori,
Ere nla iwaju wa,
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pelu Stefen' t'o ku,
Y'o ri o bi O ti duro,
Lati pe wa lo s'orun.