Search

Showing posts with label Wa s'odo mi Oluwa mi. Show all posts
Showing posts with label Wa s'odo mi Oluwa mi. Show all posts

Tuesday, 13 October 2015

WA S'ODO MI, OLUWA MI

Verse 1
WA s'odo mi, Oluwa mi,
Ni kutukutu owuro;
Mu kero rere so jade,
Lat'inu mi soke orun.

Verse 2
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni wakati osan gangan;
Ki'yonu ma ba se mi mo,
Won a si s'osan mi d'oru.

Verse 3
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Nigba ti ale ba n lẹ lo;
Bi okan mi ba n sako lo,
Mu pada; f'oju 're wo mi.

Verse 4
Wa s'odo mi, Oluwa mi
Ni oru, nigba ti orun,
Ko woju mi; je k'okan mi
Ri sinmi je ni aya Re.

Verse 5
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni gbogbo ojo aye mi;
Nigba ti emi mi ba pin,
Ki n le n'ibugbe lodo Re.


English - Come to me, Lord, when first I wake