Search

Tuesday 13 October 2015

Ewe ti Oba Orun

Verse 1
Ewe ti Oba orun,
Korin didun b'e ti nlo;
Korin in Olugbala
Ologo n'nu ise Re.

Verse 2
A nlo sodo Olorun
L'ona t'awon baba rin;
Won si nyo nisisiyi,
Ayo won l'awa o ri.

Verse 3
Korin, agbo kekere,
E o simi n'ite Re
Ib'a pese 'joko yin,
Ibe si n'ijoba yin

Verse 4
Woke, omo imole
Ilu Sion wa lokan
Ibe n'ile wa titi
Ibe l'a o r'Oluwa

Verse 5
Ma sa, e duro, l'ayo
Ni eti ile ti yin
Kristi Omo Baba nwi
Pe, laifoya k'a ma lo

Verse 6
Jesu, a nlo l'ase Re
A ko 'hun gbogbo sile
Iwo ma j'amona wa
A o si ma ba O lo


English- Children of the heavenly King

No comments:

Post a Comment