Search

Thursday 8 October 2015

JI OKAN MI

“Emi tikarami yoo ji ni  kutukutu”
Ps. 108:2

Verse 1
JI, okan mi, ba orun ji
Mura si ise oojo re;   
Mase ilora, ji kutu,
K'o san gbese ebo ooro.


Verse 2
Ro gbogb' ojo t'o fi sofo;
Bere si rere 'se loni;
Kiyes' irin re laye yi;
K'o si mura d'ojo nla ni.

Verse 3
Gba ninu imole orun,
Si tan 'mole na f'elomi,
Je ki ogo Olorun re,
Han n'nu wa ati ise re.

Verse 4
Ji, gbon 'ra nu 'wo okan mi
Yan ipo re larin Angel,
Awon ti won n korin iyin,
Ni gbogbo oru s'Oba wa.

No comments:

Post a Comment