Verse 1
OLUWA mi, mo njade lo,
Lati se ise ojo mi;
Iwo nikan l' emi o mo,
L' oro, l' ero ati n' ise.
Lati se ise ojo mi;
Iwo nikan l' emi o mo,
L' oro, l' ero ati n' ise.
Verse 2
Ise t' O yan mi l' anu Re
Je ki nle se tayotayo;
Ki nr' oju Re n'nu ise mi,
K' emi si fi ife Re han.
Je ki nle se tayotayo;
Ki nr' oju Re n'nu ise mi,
K' emi si fi ife Re han.
Verse 3
Dabobo mi lowo 'danwo,
K' O pa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aiye yi,
Ati gbogbo ifekufe.
K' O pa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aiye yi,
Ati gbogbo ifekufe.
Verse 4
Iwo t'oju Re r' okan mi,
Ma wa lowo otun mi lai,
Ki nma sise lo l' ase Re,
Ki nf' ise mi gbogbo fun O.
Ma wa lowo otun mi lai,
Ki nma sise lo l' ase Re,
Ki nf' ise mi gbogbo fun O.
Verse 5
Jeki nreru Re t'o fuye,
Ki nma sora nigbagbogbo,
Ki nma f' oju si nkan t' orun,
Ki nsi mura d' ojo ogo.
Ki nma sora nigbagbogbo,
Ki nma f' oju si nkan t' orun,
Ki nsi mura d' ojo ogo.
Verse 6
Ohunkohun t' O fi fun mi,
Jeki nle lo fun ogo Re,
Ki nf' ayo sure ije mi,
Ki mba O rin titi d' orun.
Jeki nle lo fun ogo Re,
Ki nf' ayo sure ije mi,
Ki mba O rin titi d' orun.
Forth in Thy name, O Lord, I go yoruba
No comments:
Post a Comment