Search

Tuesday 13 October 2015

Ogo ni f'Oluwa t'o se ohun nla

Verse 1
Ogo ni f'Oluwa t'o se ohun nla
Ife lo mu k'O fun wa ni omo Re
Eni t'O f'emi Re lele f'ese wa
T'o si silekun iye sile fun wa

Chorus
Yin  Oluwa, Yin Oluwa
F'iyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa
Eyo niwaju Re
K'a to Baba wa lo l'Oruko Jesu
Jek'a joo f'ogo fun, Onise 'yanu

Verse 2
Irapada kikun ti eje Re ra
F'eneikeni t'o gba ileri Re gbo
Enit' o buruju b'o ba le gbagbo
Lojukannna yo ri idariji gba

Chorus
Yin  Oluwa, Yin Oluwa
F'iyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa
Eyo niwaju Re
K'a to Baba wa lo l'Oruko Jesu
Jek'a joo f'ogo fun, Onise 'yanu

Verse 3
O s'ohun nla fun wa, o da wa l'ola
Ayo wa di kikun ninu Omo Re
Ogo ati ewa irapada yi
Y'oya wa lenu 'gbata ba ri Jesu

English-To God be the glory

Eje k’a f’inu didun

Verse 1
Eje k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 2
On nipa agbara Re
F’imole s’aye titun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 3
O mbo gbogb’eda ‘laye
O npese fun aini won
Anu re, O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 4
O npese f’ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu re O wa titi
Lododo dajudaju

Verse 5
E je k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju.

English-Let us with a gladsome mind

OLORI Ijo t'orun

Verse 1
OLORI Ijo t'orun,
L'ayo l'a wole fun o,
K'O to de, Ijo t'aye,
A gbe okan wa s'oke,
Ni 'reti t'o ni 'bukun;
Awa kigbe, awa f'iyin,
F'olorun igbala wa.

Verse 2
'Gba t'a wa ninu iponju,
T'a n koja ninu ina,
Orin ife l'awa o ko,
Ti o n mu wa sunmo o,
Awa sope, a si yo,
Ninu ojurere Re;
Ife t'o so wa di Tire;
Y'o se wa ni Tire lai.

Verse 3
Iwo mu awon eniyan Re,
Koja isan idanwo;
A ki o beru wahala,
'Tori O wa nitosi;
Aye, ese, at'esu,
Koju 'ja si wa lasan,
L'agbara Re, a o segun,
A o si ko orin Mose.

Verse 4
Awa f'igbagbo r'ogo,
T'O tun n fe fi wa si:
A kegan aye 'tori,
Ere nla iwaju wa,
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pelu Stefen' t'o ku,
Y'o ri o bi O ti duro,
Lati pe wa lo s'orun.

Awa f'ori bale fun O Jesu

Verse 1
Awa f'ori bale fun O Jesu
'Wo ti s'Olori Ijo, awon enia Re
Ijo ti mbe laye yi, ati lorun pelu
Alleluya!

Verse 2
'Wo t'o ku si jinde fun wa
T'o mbe lodo Baba bi Alagbawi wa
K'ogo at'ola le je Tire
Alleluya!

Verse 3
Ati ti ojo nla Pentikosti
Ti o ran Parakiti si aye
Olutunu nla Re ti mba wa gbe
Alleluya

Verse 4
Lat'ori ite Re l'oke orun
L'O si nwo o gbogbo awon o jise Re
T'O si nsike gbogbo awon
Ajeriku Re
Alleluya!

Verse 5
A fi iyin at'olanla f'oruko Re
N'tori iku gbogbo awon ojise Re
Ni gbogbo ile yi
Alleluya!


English-We adore Thee O Lord

GBOGBO aye, gbe Jesu ga

Verse 1
GBOGBO aye, gbe Jesu ga,
Angel, e wole fun;
E mu ade Oba Re wa,
Se l'Oba awon Oba.


Verse 2
E se l'Oba, eyin Martyr,
Ti n pe ni pepe Re;
Gbe gbongbon-igi Jesse ga,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 3
Eyin iru-omo Israel,
Ti a ti rapada;
E ki eni t'o gba yin la,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 4
Gbogbo eniyan elese,
Ranti 'banuje yin;
E te 'kogun yin s'ese Re,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 5
Ki gbogbo orile-ede,
Ni gbogbo agbaye;
Ki won ki, “Kabiyesile”,
Se l'Oba awon Oba.

Verse 6
A bale pel'awon t'orun,
Lati ma juba Re;
K'a ba le jo jumo korin,
Se l'Oba awon Oba.


English-All hail the power of Jesus' name

Ewe ti Oba Orun

Verse 1
Ewe ti Oba orun,
Korin didun b'e ti nlo;
Korin in Olugbala
Ologo n'nu ise Re.

Verse 2
A nlo sodo Olorun
L'ona t'awon baba rin;
Won si nyo nisisiyi,
Ayo won l'awa o ri.

Verse 3
Korin, agbo kekere,
E o simi n'ite Re
Ib'a pese 'joko yin,
Ibe si n'ijoba yin

Verse 4
Woke, omo imole
Ilu Sion wa lokan
Ibe n'ile wa titi
Ibe l'a o r'Oluwa

Verse 5
Ma sa, e duro, l'ayo
Ni eti ile ti yin
Kristi Omo Baba nwi
Pe, laifoya k'a ma lo

Verse 6
Jesu, a nlo l'ase Re
A ko 'hun gbogbo sile
Iwo ma j'amona wa
A o si ma ba O lo


English- Children of the heavenly King

BABA MI GBO TEMI

Verse 1
BABA mi gbo temi
'Wo ni Alabo mi,
Ma sunmo mi titi;
Oninure julo!

Verse 2
Jesu Oluwa mi,
Iye at'ogo mi,
K'igba naa yara de,
Ti n o de odo Re.

Verse 3        
Olutunu julo,
'Wo ti n gbe inu mi,
'Wo to mo aini mi,
Fa mi, k'o si gba mi.

Verse 4
Mimo, mimo, mimo,
Ma fi mi sile lai,
Se mi n'ibugbe Re,
Tire nikan lailai.


English-Holy Father, hear me

WA S'ODO MI, OLUWA MI

Verse 1
WA s'odo mi, Oluwa mi,
Ni kutukutu owuro;
Mu kero rere so jade,
Lat'inu mi soke orun.

Verse 2
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni wakati osan gangan;
Ki'yonu ma ba se mi mo,
Won a si s'osan mi d'oru.

Verse 3
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Nigba ti ale ba n lẹ lo;
Bi okan mi ba n sako lo,
Mu pada; f'oju 're wo mi.

Verse 4
Wa s'odo mi, Oluwa mi
Ni oru, nigba ti orun,
Ko woju mi; je k'okan mi
Ri sinmi je ni aya Re.

Verse 5
Wa s'odo mi, Oluwa mi,
Ni gbogbo ojo aye mi;
Nigba ti emi mi ba pin,
Ki n le n'ibugbe lodo Re.


English - Come to me, Lord, when first I wake

WA S'ADURA OORO

Verse 1
WA s'adura ooro,
Kunle k'a gbadura;
Adura ni opa Kristiani,
Lati b'Olorun rin.

OLUWA MI, MO NJADE LO

Verse 1
OLUWA mi, mo njade lo,
Lati se ise ojo mi;
Iwo nikan l' emi o mo,
L' oro, l' ero ati n' ise.

Friday 9 October 2015

THROUGH ALL THE DANGERS OF THE NIGHT

Verse 1
Through all the dangers of the night
The Lord doth keep me safe
To see another morning dawn
And to bow down the knee

Verse 2
Oh Lord we pray keep us today
Beneath Thy mighty wings
Only the ones whom Thou doth keep
Are from all dangers free

Verse 3
Let all our thoughts and all our deeds
Show we belong too Thee
So that our light may truly shine
And beam to all the world

Verse 4
O grant that we ne'er stray from Thee
Jesus, Saviour Divine
Until our eyes there shall behold
Thy face for ever more
AMEN


Yoruba - Ninu gbogbo ewu oru

IMOLE ORO DIDUN YI

Verse 1
Imole oro didun yi
Ji mi nin'orun mi
Baba, ife Tire nikan
L'o pa omo Re mo

Verse 2
Ni gbogbo oni, mo be o
Ma se Oluso mi
Dariji mi, Jesu mimo
Ki'n je Tire loni

Verse 3
Wa se 'bugbe Re ninu mi
Emi ore-ofe!
So mi di mimo laye yi
K'emi le r'oju Re

THE MORNING BRIGHT WITH ROSY LIGHT

Verse 1
The morning bright with rosy light
Has waked me from my sleep
Father, I own Thy love alone
Thy little one doth keep

Verse 2
All Thou the day, I humbly pray
Be Thou my guard and guide
My sins forgive, and let me live
Lord Jesus, near Thy side

Verse 3
Oh make Thy rest within my breast
Great Spirit of all grace
Make me like Thy, then shall I be
Prepared to see Thy face.

Thursday 8 October 2015

JI OKAN MI

“Emi tikarami yoo ji ni  kutukutu”
Ps. 108:2

Verse 1
JI, okan mi, ba orun ji
Mura si ise oojo re;   
Mase ilora, ji kutu,
K'o san gbese ebo ooro.

AWAKE MY SOUL



Verse 1

Awake, my soul, and with the sun

Thy daily stage of duty run

Shake off dull sloth and joyful rise

To pay thy morning sacrifice